r ará lú (Live)-文本歌词

r ará lú (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Mo recognise presence DCP

Ọ̀gá wa máa wolẹ̀, máa ràba

Deputy Commissioner of Police NÍ Lagos state

Bó bá jẹ t’operations, ìwọ ni

Ọwọ́ ẹ ló wà Arabambi

Ọmọ Titilayo Káyọ̀dé o, ọkọ Kẹ́mi Kẹ́mi sweetie ayaba

Ọlá bàbá Kóredé mi bàbá Deji Deji

Alápọ̀ńlé èèyàn, bí ẹ bá ri nínú iṣẹ́ Ọba

Ìwà ṣá lẹ ó ti mọ̀

Orí á gbé ẹ dé ipò ńlá, ọmọ Titilayọ̀ mi Káyọ̀dé o

Bàbá ti ọmọ méjì mi ẹdúnjọbí mi

Bàbá ẹdúnjọbí ọmọ méjì

Ọkọ ti Kẹ́mi Kẹ́mi sweetie ayaba

Bàbá Kóredé mi bàbá Deji mi

Titilayọ̀ Káyọ̀dé o, ṣe ò ń bá mi tọ́jú CP

Ọ̀gá wa ní Lagos State, a dẹ̀ kú ìpalẹ̀mọ́ ti ìyàwó ọmọ wọn

On the 20th of May, 2017

Tó o bá délé o bá mi ki

Abdulfatai mi ko ma ki dáadáa

Ọmọ Owóṣeéní Fatai tèmi

Titilayọ̀ Káyọ̀dé (Káyọ̀dé)

Ọ̀rẹ́ ará ìlú, ọwọ́ ẹ̀ ni gbogbo operations

Lagos State police Command ọwọ́ ẹ ló wà (Káyọ̀dé)

Bí àwọn ọmọ burúkú bá gbọ́ orúkọ ẹ

Wọ́n á m’órí mù, gbogbo wọn á sáré wọ corner (Titilayọ̀ Káyọ̀dé)

Ẹ ẹ̀ dẹ̀ lè ri lójú ẹ̀ pé ó ń bínú

Èèyàn tó bá ti ń ṣiṣẹ́ Ọba tó bá wà

t’óyìnbó wí, tó láàánú lójú

Kò ní wa gbogbo iṣẹ́ mọ́ àyà

Kò ní mu lójú koro koro koro pẹ̀lú agídí

Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, á dẹ̀ máa ṣiṣẹ́ yẹn o

Á máa ní àṣeyọrí lágbára Ọlọ́hun Ọba

Wàá di commissioner lójú irú wa

Wàá di AIG lójú irú wa

Wàá di DIG lójú irú wa

Tó bá wá wu Ọlọ́hun Ọba, tó jẹ́ bí àdéhùn

Láàrin Ẹlẹ́dàá àti Ọlọ́hun Ọba, wàá di Inspector General of Police

Àwa ń tọrọ ni, Ọlọ́hun ló máa fi àṣẹ si

A tọrọ fún ará iwájú, Ọlọ́hun gbọ́ àdúrà wa o

Èèyàn ire tó bá ń bẹ nínú iṣẹ́ Ọba àdúrà ni ẹ ṣe fun

Titilayọ̀ ọmọ Káyọ̀dé, àdúrà ẹ á máa gbà o

Deputy Commissioner of Police ọkọ Kẹ́mi Kẹ́mi sweetie ayaba

Akeme Baby mi olóríire aya Ọba

Ìyẹn awo tèmi Àyìndé Wasiu Arábámbí

Aya Káyọ̀dé mi ọ̀gá wa

Titilayọ̀ Káyọ̀dé (Titilayọ̀ Káyọ̀dé)

Gbogbo ìgbà tí òde bá burú o ò ní jáde lé ikú lọ́wọ́ o

Ọlọ́hun bá mi ṣọ́ ẹ lọ́sàn-án lóru

Titilayọ̀ ọmọ Káyọ̀dé, alágbèédá kò ní gbé ẹ ò, kò ní gbé ẹ dá

Ìṣọ́ Ọlọ́hun ní ìgbà gbogbo

Ọkọ Kẹ́mi (ọkọ Kẹ́mi)

Ọkọ Kẹ́mi (ọkọ Kẹ́mi)

Titilayọ̀ ń bọ̀ o (Bàbá ń bọ̀ o)

Káyọ̀dé ń bọ̀ o (Bàbá ń bọ̀ o)

Titilayọ̀ ń bọ̀ o (Bàbá ń bọ̀ o)

Gbogbo ẹ̀yin ọmọ burúkú, ẹ mórí nù ẹ sáré wọ’gbó (Bàbá ń bọ̀ o)

Ẹ̀yin ọmọ burúkú, ẹ mórí nù ẹ sáré wọ igbó (Titilayọ̀ bàbá ń bọ̀ o)

Deputy Commissioner of Police (Bàbá ń bọ̀ o)

Deputy Commissioner of Police (Titilayọ̀, Bàbá ń bọ̀ o)

Lagos State member Operations (baba ń bọ̀ o)

Gbogbo ẹ̀yin ọmọ burúkú, ẹ mórí nù ẹ sáré wọ’gbó (Bàbá ń bọ̀ o)

Ẹ̀yin ọmọ burúkú, ẹ mórí nù ẹ sáré wọ igbó (Titilayọ̀ bàbá ń bọ̀ o)

Ẹ parẹ́, ẹ fara ṣoko, ẹyin ọmọ burúkú (Bàbá ń bọ̀ o)

Titilayọ̀ baba ń bọ̀ o (Titilayọ̀ baba ń bọ̀ o)

Titilayọ̀ ń bọ̀ o (baba ń bọ̀ o)

Awo Fatai ọmọ Owóṣeéní (Titilayọ̀ baba ń bọ̀ o)

Ṣe Ìtọ́jú CP wa (Títí bàbá ń bọ̀ o)

Ṣe Ìtọ́jú CP wa (Títílayọ̀ bàbá ń bọ̀ o)

DCP Operations Lagos State ọkọ Kẹ́mi

(DCP Operations Lagos State ọkọ Kẹ́mi)