Azeez, ọmọ amuda mi Yusufu
Ọmọ ilé olódó, ilé olódò
Ní’lọrin Àfọ̀njá o
Nílé olódò, Ìlọrin Àfọ̀njá o
Azeez Ìlọrin ń bẹ o (Àfọ̀njá ń bẹ)
Ọkọ ni ní ń ṣọlá
Èdùmàrè ní ń ṣògo
Ṣò ń gbangba títì, ká yíra wa mọ́lẹ̀
Bá a yíra wa mọ́lẹ̀ tán o
Ká bọ́ gbangba motor
Epo ló ni jàgo (ẹ̀wọ̀n ló ni olè jíjà)
(láàlú ló láró, àmọ́ gbogbo ẹ̀, gbògbò ẹ̀ yí ó tó ọ pẹ́)
Epo ló ni jàgo (ẹ̀wọ̀n ló ni olè jíjà)
(láàlú ló láró, àmọ́ gbogbo ẹ̀, gbògbò ẹ̀ yí ó tó ọ pẹ́)
Ẹ sìn mí dé Ìlọrin ò eh
Ẹ sì mí dé Ìlọrin o ah
Ìlọrin Àfọ̀njá o, ẹ sìn mí dé Ìlọrin
(Ẹ sìn mí dé Ìlọrin o eh)
(Ẹ sìn mí dé Ìlọrin o ah)
(Ìlọrin Àfọ̀njá o, ẹ sìn mí dé Ìlọrin)
Ìlọrin Àfọ̀njá o, (ẹ sìn mí dé Ilorin)
Ẹ sìn mí dé Ìlọrin ò eh
Ẹ sì mí dé Ìlọrin ò ah
(Ìlọrin Àfọ̀njá o, ẹ sìn mí dé Ìlọrin)
Ìlọrin Àfọ̀njá o (ẹ sìn mí dé Ilorin)
Ọkọ mi sọ pé mo kéré (ó fi mí lẹ̀ ó r’ogun)
Àlè mi pé mo kéré (ó fi mí lẹ̀ ó r’ọ̀sà)
Kí ló tòkun tọ̀sà dé (mo b’ọ́mọdé ẹlòmíì lọ)
Aláago lọ́wọ́ ń bẹ ní Ìjẹ̀bú òde o (eh ba)
Àyìndé ‘mọ́gbọ́láhàn arábámbí ẹ ṣeun
Tí n bá ti ki Azeez, tó bá jó tán n ó dánu dúró
Irin iṣẹ́ yìí ò tẹ́mi lọ́rùn arábámbí
Ẹ ẹ̀ lé gb’orin mọ́ mi lọ́wọ́
Tí gbogbo ẹ̀ ń kùn tó ń kùn yìí
Àyìndé arábámbí
Olúayé onífújì
…
Oṣé modúpẹ́ Amuda mi Yusu, amuda mi Yusufu
Amuda mi Yusufu aláàánú
…
Orí mi mọ́gbọ́láhàn kò ní burú
(Arabic recitation)