gé Dé (Live)-文本歌词

gé Dé (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Mo mọ̀ ọ́ lóore

Ẹni a bá ṣe lóore bí ò bá dúpẹ́

Bí ọ̀lọ́ṣà kẹ́rù ẹni lọ ni

Àyìndé mi Wasiu Arábámbí

Ògé dé Ọba ẹyẹ

Àyìndé dé o o o Ọba orin o

Oríyọmí bó o bá délé bá mi kí Tolú

Àní Ògé dé Ọba ẹyẹ

Aláyìndé dé o Ọba orin o

Ẹ wọlé ire ẹ f’ògé sí o ohun gbogbo lọ́wọ́ orí

White ẹ dà?

Mo kàn fẹ́ kó bá mi kí ọ̀rẹ́ mi bó bá délé

Yẹ̀kínì Àjàó, Ọlọ́hun tó ṣe adé orin tó ṣe fún bàbá ẹ dàgbàsókè

Yẹ̀kínì Yk Àjàó méjì ni ti ẹ̀ lọ́dọ̀ Àyìndé

Ọ̀rẹ́ mi ló jẹ́ láti kékeré a jọ jẹ́ ọ̀rẹ́

Ẹ̀gbọ́n mi ló tún jẹ́, Professor YK mi

Ṣùgbọ́n a d’ọ́rẹ̀ẹ́ láti kékeré, a dẹ̀ jọ ń ṣe dáadáa ní kékeré wa

Àwa mẹ́rin kan la jọ ń rìn Yk Àjàó, èmi Arábámbí, Sir Shina Peters mi àti Adéwálé

A dẹ̀ ṣe dáadáa ní kékeré

À ń kó’ra wa kiri gbogbo wa l’Ọlọ́hun kẹ́ a rọ́pẹ́ dá

Àjàó Yẹ̀kínì ko bá mi ki sílé l’ẹ́bẹdí Ìsẹ́yìn òrò mi

Ìlú Oríyọmí Aminatu mi

Àjàó Yẹ̀kínì bó o bá ń gbọ́ nílé mo fi gbogbo ara kí ẹ professor YK mi Àjàó

Ojúlówó ọmọ ló jẹ́ fún Chief Ebenezer Àrẹ̀mú adé Bàbá wa

Baàmi Obey Commander Rẹ̀mílẹ́kún

Ojúlówó ọmọ Commander ni Professor YK Yẹ̀kínì Àjàó adé tèmi

Èmi jẹ́ ọmọ ọmọ fún Ebenezer mi Àrẹ̀mú adé

Torí pé mo j’ọ́mọ fún Sikiru SK o àti sir Shina Peter arábámbí

Adúpẹ́ Ọlọ́hun o mà ṣeun

Oore tó ṣe fún mi Wasiu Àyìndé

Akin ọmọ Arógundádé ọ̀rọ̀ tí mò ń wí

Àpò ṣáṣámùrá ò é ṣáṣámùrá ò gbẹ rí

Àpò tí ẹ bá ń tọwọ́ bọ̀ tí gbogbo yín ti ń mówó

Ṣáṣámùrá àpò ṣáṣámùrá àpò ṣáṣámùrá

Àpò ṣáṣámùrá ò gbẹ rí ṣáṣámùrá o

Akin ọmọ Arógundádé

Láti ibi dé ìlú Holland kọjá re London Arábámbí

Èèyàn AbdulWazir òyìnbó elépo

Àní ẹjọ́ òun ẹlẹ́jọ́

Ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ láyé ń bí kò ní dẹ̀bi mọ́ wa lọ́wọ́

Ẹ̀lúkú b’óore bá pọ̀ á dẹ̀bi Wasiu Àyìndé o

Akin ọmọ Arógundádé gbogbo ẹ̀yin tó ń lọ sí Holland

Ẹ máa bá mi kí Túnjí ọmọ Oláníihún

Ìyẹn Túnjí Kashoki mi àti Gbóyè mi

Gbénga ọmọ Ọláníihún àwọn méjèèjì àbúrò Káyọ̀dé o

Káyọ̀dé ọmọ Ọláníihún

Ó wá ń dára báyìí o o Àjàní

Mo wá bẹ̀ ẹ́ Ọlọ́hun Ọba má fi kíkan sọ̀rọ̀ rẹ o

Kó o má j’egungun lẹ́yìn ẹran

Ṣótirẹ̀, ọ̀rọ̀ tí mò ń wí àpò ṣáṣámùrá o é ṣáṣámùrá ò gbẹ rí

Akin ọmọ Arógundádé

Àpò ṣáṣámùrá o

Ẹ bá mi pé á mà ṣẹ ò (Àṣẹ)

%Bá mi pé á mà ṣẹ o (Àṣẹ)

Bá mi pé á mà ṣẹ o (Àṣẹ)

Iré dé iré dé o Ọba Fújì General

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Àyìndé mi Gbọ́láhàn arábámbí Olúayé onífújì o

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Iré dé iré dé o

Iré dé iré dé o Ọba Fújì General

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Modinatu máa wolẹ̀ mother t’ẹdúnjọbí mi màmá ọmọ méjì o

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Tọ́pẹ́ baby mi máa wolẹ̀ máa ràba aya Àyìndé mi Siliu

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Bẹ délé kẹ kí ọmọ mi Aishatu mi ṣágbọlá ọmọ Ọ̀gọ́jì o

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Àwọn aya Àyìndé Musiliu Ayédáadé o Àyìndé tì ẹ yàtọ̀ o

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Modinatu mother t’ẹdúnjọbí mo mà kí ẹ kí ẹ Modinatu mi

Owó màmá ọmọ méjì o

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Aṣíwájú ni ẹ́, o ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn sweetie Modinatu o

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Aya Àyìndé Musiliu Ayédáadé Àyìndé tì ẹ yàtọ̀ o

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Ṣètọ́jú gbóyè mi àti Zainab mi sweetie Modinatu o

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Ọba tó lòkun lọ̀sà ò mà ní jẹ́ ẹ tẹ́ o Allahu Rabi á tì yín lẹ́yìn o

(Iré wọlé dé Ọba Fújì General o)

Àyìndé jẹ́ mi ní hẹn kí n gbọ́ o (hẹn)

Ayédáadé ko jẹ́ mi ní hẹn kí n gbọ́ o (hẹn)

Àyìndé ewé ayò (hẹn)

Ewé itún méje (hẹn)

Itún ló ní kí wọ́n tún ẹ ṣe (hẹn)

Ìfà ló ní kí wọ́n fà ẹ́ mọ́ra (hẹn)

À ìí bínú k’ogún ataare (hẹn)

Mo gún méjì ọkàa bàbà (hẹn)

Mo gún mẹ́ta ọkàa wasẹ́ (hẹn)

Orí ló ń túmọ̀ ẹnu (hẹn)

Gbòǹgbò ọ̀nà ní ń túmọ̀ ẹsẹ̀ (hẹn)

Ìmọ̀ tú ìmọ̀ jọ (hẹn)

Ìmọ̀ ebirí wọn kì í dálẹ́ (hẹn)

Bí wọ́n bá lọ mẹ́lẹ́mọ́ (hẹn)

Wọ́n á fi joyè ẹlẹ́mọ́ (hẹn)

Bí wọ́n bá lọ m’éfinrin (hẹn)

Wọ́n á fi joyè ẹrùkú (hẹn)

B’ọ́wọ́ wọn bá tẹ’pín wọ́n á fi joyè aláre (hẹn)

Musiliu Àyìndé àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta parapọ̀ (hẹn)

Wọ́n wá jọ ń pẹmọ́ (hẹn)

Tọ́pẹ́ ẹmọ́ ò lókoo jẹ (hẹn)

Wọ́n ń p’Akíntọ́lá (hẹn)

Akíntọ́lá ọmọ Ògún (hẹn)

Wọ́n ń p’ajíyọdà (hẹn)

Ọmọ àkàràmọbà (hẹn)

Aisha wọ́n ń p’ajíṣàdadadẹ (hẹn)

Ọmọ’ba Ìjẹ̀bú mère (hẹn)

Ó d’ògbolù kẹ̀rẹ̀ (hẹn)

Ajagun ló lòde ọ̀run (hẹn)

Tóyìn bó bá ṣe pé tì ẹ (hẹn)

Ni wọ́n bá ń dáríjọ wí (hẹn)

Àgbéró nikú ń gbọ́wọ́ (hẹn)

Ọ̀gọ tí ṣìgìdì bá gbé (hẹn)

Àgbétì ló máa ń gbe (hẹn)

Àyantì la yan ewúrẹ́

Ọlọ́hun dákun má padà lẹ́yìn ẹ

(Kó má gbàgbé ọ̀rọ̀ tẹ jọ sọ)

Aya President National Union Of Road Transport Workers

Modina Ọlọ́hun dákun má padà lẹ́yìn ẹ

(Ko má gbàgbé ọ̀rọ̀ tẹ jọ sọ)

Toppytime, Tọ́pẹ́ Ọlọ́hun dákun má padà lẹ́yìn ẹ

Ko má gbàgbé ọ̀rọ̀ tẹ jọ sọ)

Ọlọ́hun dákun má padà lẹ́yìn gbogbo wa

(Ko má gbàgbé ọ̀rọ̀ ta jọ sọ)

Aya Ayédáadé Musiliu o Àyìndé tì ẹ yàtọ̀ o

Ayédáadé Musiliu o Àyìndé tì ẹ yàtọ̀

A kì mà í lẹ́ni nímọsàn àní ká mu kíkan Àyìndé tìẹ yàtọ̀ o

Ayédáadé Aláyìndé mo kí ẹ kí ẹ o ọmọ L’Àyìndé Akínsànyà

Ó ṣe ọdún eléyìí tọmọ tọmọ ni wàá ṣe ẹ̀míì si Àyìndé Musiliu o

Aya t’Àyìndé mi Musiliu (Ayédáadé)

Ẹ yá mi létí yín

Tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ ẹ máa ń ṣẹ́nu pè é

Ẹni láti máa fi kun láti ìsín

Tí ẹ bá máa pè é

Bí ẹ bá máa pe Àyìndé mi Musiliu egungun Ayédáadé

Musiliu lòun ń jẹ́, Àyìndé ló ń jẹ́

Ó ń jẹ ọmọ Akínsànyà

Oníkálukú ló nílé

Òòṣà ìdílé mi, mi ò lè f’0ọwọ́ yẹ̀ ẹ́ o

Ìdílé olórìṣà l’arábámbí

Àyìndé mi Musiliu (egungun Ayédáadé)

Ṣé ẹ rí’ṣẹ́? Ṣé ẹ rí’ṣẹ́? Òríìrì ré

Ẹ̀fúùfùlẹ̀lẹ̀ tó ń ṣe ewé oko

Ah ah Àyìndé mi Musiliu (egúngún Ayédáadé)

Àyìndé mi Musiliu (egungun Ayédáadé)

Ọkọ Sweetie Modina (egungun Ayédáadé)

Ah! Ọkọ Tọ́pẹ́ baby mi (egungun Ayédáadé)

Àyìndé ọkọ Aishatu (egungun Ayédáadé)

Àyìndé mi Musiliu (egungun Ayédáadé)

Ẹ̀yin tí ń perí wa láìda o