Sokopa (Live)-文本歌词

Sokopa (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Easy Koboko, ó tún mówó wá

Gbogbo ìgbà tí ń bá rí ẹ Ọmọ́gbọ́láhàn mi

N ó máa ṣe àdúrà fún ẹ ni

Àpọ́nlé lara ń fẹ́ ara ò mà fẹ́ àbùkù o

Ọlọ́hun kó wo ọlá gbogbo ẹni tó ń dùn nínú

Dende, kòní jẹ́ kí ti ìwọ náà kó gbé o

Ọkọ Lará, Yọ̀mí ọjọ́ọ̀la ó ń náwó, owó Dende ló ń ná

Gbogbo yín pátápátá tí ẹ tọwọ́ b’àpò tí ẹ m’ówó Dende wá

Tiyín náà ò ní bàjẹ́ Arábámbí

Gbogbo wa la ó dunnú délẹ̀

Ọlọ́hun Ọba kó tijú Dende mọ́ gbogbo wa lara àdúrà á máa gbà o

Bẹ́ẹ̀ bá wá jayé títí ó, ẹ bá mi tọ́jú Ọbasanjọ́

(Ọbásanjọ́)

Fágbohùn bàbá tèmi Àyìndé Wasiu (Ẹ tọ́jú Ọbásanjọ́)

Bàbá tèmi Àyìndé Wasiu (Ẹ tọ́jú Ọbásanjọ́)

Ẹ tọ́jú Sokopa (Sokopa)

Gaduku Akuma (Sokopa)

Owó yìí owó Àdìgún, Owó Sokopa (Sokopa)

Easy Koboko (Sokopa)

Owó Sokopa (Owó Sokopa)

Owó Sokopa (Owó Sokopa)

Kiníkan kan tí mo mọ̀, tó máa ń wú mi lórí

Owó ara wọn tí wọ́n ń bá ń na báyìí pẹ̀lú inú dúndùn gẹ́gẹ́ bí orúkọ tí wọ́n ń jẹ́

Inúmidùn ká ṣá máa ṣ’ọ̀rẹ́ ara Àyìndé o

(Káṣá máa ṣ’ọ̀rẹ́ ara, ọ̀rẹ́ ni Ọba Ọlọ́hun bá Muhammed ṣe o)

Inúmidùn àwọn agúnbàjẹ́ ò lódó

(Olodo, agúnbàjẹ́ ò lódo)

(Ẹnu lásán lodó wọn gbogbo aṣèbàjẹ́ ẹ kú, ẹ mà kú ọ̀fọ̀ o)

Wọ́n ó le, wọn ò le è ba o

(Wọ́n ó le, wọn ò le è bá)

Ẹti lọ mọ́ wọn lọ́wọ́, gbogbo inúmidùn

(Wọ́n ó le, wọn ò le è ba)

Inúmidùn mo bá lọ Wasiu Àyìndé o

Ẹni bá wù ló le wú o

(Inúmidùn mo bá lọ Wasiu arábámbí)

Murphy Ìjẹ̀bú, béèyàn bá tọ́ Ọmọọlọ́mọ

Tọ́mọ náà bá ṣe oríire

Murphy Ìjẹ̀bú, béèyàn bá tọ Ọmọọlọ́mọ tó bá yàn tó yanjú

Ọlọ́hun á tọ́ ti ẹ̀ Àmín

Ìjẹ̀bú mi Murphy mi, Murphy Ìjẹ̀bú o

Murphy Ìjẹ̀bú ní kí n báwọn dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ẹgbẹ́

Ẹ kú àdúrótì Sulemona Yoboro, ọmọ Omídínà Àkànní Ade

Sule Yoboro (Sule Yoboro)

Òun náà nílùú, Yoboro mi Sule

(Sule Yoboro, Sule Yoboro)

Ọmọ Omídínà, ẹ tún ìlù ẹ̀ lù

Sule Yoboro (Yoboro, Sule Yoboro)

Ọmọ Omídínà (Sule Yoboro Sule Yoboro)

Ọkọ Afusa o káre o (Sule Yoboro Sule Yoboro)

Ó yá omi làbùwẹ̀, omi làbùmu

Omi Làbùwẹ̀ (omi làbùmu)

Sule, omi Làbùwẹ̀ (omi làbùmu)

Omídínà omi Làbùwẹ̀ (omi làbùmu)

Omi Làbùwẹ̀ (omi làbùmu)

Ọkọ Afusa omi làbùwẹ̀ (omi làbùmu)

Omi Làbùwẹ̀ (omi làbùmu)

Aláṣẹ SLAB motor omi Làbùwẹ̀ (omi làbùmu)

Yoboro mi Sule

(Sule Yoboro Sule Yoboro)

Ọmọ Omídínà

Omi Làbùwẹ̀ omi làbùmu

SLAB motor Yoboro

Òyìnbó elépo Yoboro

Sule Yoboro (Sule Yoboro)

Omídínà, Omídínà, Omídínà, Omídínà, Omídínà, Omídínà, Omídínà

Olówó ni Sule (Sule Maito)

Ọmọ Omídínà, ọkọ Afusa olówó ni Sule (Sule Maito)

Òyìnbó elépo (Sule Maito)

Omídínà, Omídínà, Omídínà, Omídínà, Omídínà, Omídínà

Ọ̀rọ̀ ẹ ó ti já sí’re, ọmọ Omídínà ọ̀rọ̀ ẹ ó ti já sí’re

Bí’re ṣe ń gbọ̀tún wọlé o, ni’re ń gba òsì wá o

(Yoboro, ọ̀rọ̀ ẹ, ó ti já sí ire)

Ọ̀rọ̀ ẹ ó ti já sí’re,

Bí’re ṣe ń gbọ̀tún wọlé o, ni’re ń gba òsì wá o

(Yoboro, ọ̀rọ̀ ẹ, ó ti já sí ire)