Lege Miami (Live)-文本歌词

Lege Miami (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Lege, ṣé ò ń bá mi tọ́jú Kamal pẹ̀lú ST

Lege Miami mo kí ẹ lege lege

Mò ń wọ́kọ pàdé mò ń wáya lọ́dọ̀ Lege

Ìwọ ọmọ obìnrin tí o bá ń wọ́kọ o

Kẹ́ ẹ ṣé jẹ́jẹ́ ẹ lọ rí Lege Miami

Èyí tí mo tiẹ̀ like jù tí wọ́n bá ń tackle ara wọn

Ìyẹn ni mo like

Àìmọye ọmọge tó mọ ohun tó fẹ́ kò dẹ̀ ń gba shit

Àìmọye ọkùnrin pàápàá ó mọ irú aya tó ń wá

Ìgbà tí ẹ bá fẹ́ra yín tán

Kí lẹ má ń mú wá fún Lege?

Alárinnà Proper alárinnà proper ni lege lege

Torí Lege tí ẹ̀ ń wò yìí ọmọ company ni

Ah! Kò dẹ̀ gba játijáti kò gba réderéde Àyìndé

Ọba hookup lege lege

Lege Miami (Ọba hookup lege lege)

Bọ́lájí Àjàní, kòsí ihun tí ò lérè (Ọba hookup lege lege)

Àjàní Bọ́lájí Bàsíà ìwọ ni bàbá Poco (Ọba hookup lege lege)

Lege èèyàn Germany Waheed (Ọba hookup lege lege)

Àwọn ti ṣómólú wọ́n ní n kí ẹ (Ọba hookup lege lege)

Òun ló represent wa ní Ṣómólú Waheed ní Ṣómólú Bariga

(Ọba hookup lege lege)

Èèyàn bolikoko ọlọ́pàá Askari tó ń kọ Fújì

Èèyàn ti lege Miami (Ọba hookup lege lege)

Àwọn ti Ṣómólú wọ́n ní n kí ẹ o (Ọba hookup lege lege)

Lege Miami àwọn ti Ṣómólú ní n kí ẹ (Ọba hookup lege lege)

Àwa ti Fákóredé a kí ẹ o (Ọba hookup lege lege)

Àwa ti Oguntolu a kí ẹ (Ọba hookup lege lege)

Àwa ti Market market road àwa náà kí ẹ (Ọba hookup lege lege)

Area mi mẹ́tẹ́ẹ̀ta nìyẹn ní Ṣómólú àwa t’Ògúntólú a kí ẹ

(Ọba hookup lege lege)

Àwa ti Fákóredé a kí ẹ o (Ọba hookup lege lege)

Ọmọ ni lege Miami (Ọba hookup lege lege)

Èèyàn Sodi Alágbo (Sodi Alágbo)

Ṣé ò ń bá mi tọ́jú Sherifi

Gbogbo yín ẹ kú ọdún

Ẹ̀mí yín á ṣe púpọ̀ọ ẹ̀ mo kíi yín

Àjàní Ọmọ́bọ́lájí ihun téèyàn bá mọ̀

Kó máa ṣé dáadáa o kó máa ṣé dáadáa

Kòsí ìhun tí ò lérè

Kò sí èyí tí ò dowó l’America

Ìdí rèé tí a ní láti gbà fún Lege

Àjàní ara àwọn ọmọ tá n wí rèé

Bí a ṣe ń sọ ti lege lọ́wọ́ Apá tún wọlé

Eléyìí náà ó bad

Àjàní ṣé ẹ wo ibi tí ẹ bá ayé dé eléyìí ah!

Chief Gaji, Gaji ó bad

Gaji ń sọ bótò Apa ń sọ yéye

Ali afisu Afisu ọmọ t’òkú ọ̀run ọkọ Mide baby

Ọmọ mi ńkọ́? Happy New Year to you

Ọmọ mi ńkọ́ nílé?

Gbogbo yín ẹ kú ọdún ẹ̀míi yín á ṣe púpọ̀ ọdún láyé

Al-Afeez Ìsẹ́yìn òrò ẹbẹdí o kú ilédè bàbá ẹ

Apá! Ọmọ alálùbáríkà ṣá ni ẹ́

Apá! O ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn o

Ọlọ́hun Ọba tó bá mi gbọ́wọ́ Fẹ́mi sókè á gbọ́wọ́ gbogbo yín sókè kò ní bàjẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba

Àdúà á máa gbà Àmín

Ah! Gaji o (Gaji o)

Gaji eléyìí ó ń sọ bótò

Gaji eléyìí ó ń sọ bótò

Bọ́lájí a ní talent ní Nigeria gbogbo wọn ló ń ṣ’oríire

Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire

Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire (gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire)

Askari gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire

(Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire)

Ìkan ò wá ní ṣe ẹrú ara wọn lọ́lá Elédùmarè

(Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire)

Ah! Ibrahim Chatta

Ìkan òní ṣe ẹrú ara wọn lọ́lá Ọlọ́hun

(Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire)

Fẹ́mi Adébáyọ̀ (gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire)

Ah! Producer wọn rèé

Afod Àjàní ṣé o rí àwọn ọmọ tí mo ń sọ o

(Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire)

Kúnlé Afod àwọn ọmọ tí mò ń sọ o

(Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire)

Bàbá aláàánú ọkọ àwọn arúgbó

Bàbá Ọ̀yọ́

Báyọ̀ máa wolẹ̀ máa ràba

Àwọn Director General

(Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire)

Adébáyọ̀ ọmọ Tijani ah ah

Máa wolẹ̀ Fẹ́mi Adébáyọ̀

(Gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣ’oríire)

Fẹ́mi ẹ̀yin lọmọ tí wọ́n ń sọ lọ́wọ́ lọ́wọ́

Ah ah

Ẹ túálè fún Èsúsú

Èsúsú mo túálè fún ẹ (Èsúsú mo túálè fún ẹ)

Mo túálè fún ẹ (mo túálè fún ẹ)

Ara àwọn ọmọ tí wọ́n ń sọ lọ́wọ́ lọ́wọ́

Èsúsú mo túálè fún ẹ (mo túálè fún ẹ)

Gbogbo yín pátá pátá Ọlọ́hun tó bá mi gbé ọwọ́ọ yín sókè

Kò ní rẹ̀yín nílé lọ́lá Ọlọ́hun Ọba

Fẹ́mi happy birthday to you o kú oríire

Ọmọ t’Adébáyọ̀ ọmọ t’Àdùkẹ́

Adébáyọ̀ ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma

Fẹ́mi ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma?

Bàbá Ọ̀yọ́ ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma?

Fẹ́mi ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma?

Ọkọ Iyán aládùkẹ́ ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma

Àyìndé Wasiu ṣé a jọ ma ṣe àmọ́dún o?

Shakada Ibro Shakada

Adébáyọ̀ ṣé a jọ ma? ṣé a jọ ma?

Òní la ó mu ọ̀la la ó mu

Okay now agbára Fẹ́mi gangan ọmọ Adébáyọ̀ congratulations

Ó ti kó gbogbo wa kéré sókè

O ti kó táyà síwa lẹ́sẹ̀

Ìwọ nìkan lo láyà aláya méje (aláya méje)

Aládùkẹ́ má fi bínú

Aládùkẹ́ má fi bínú

Aláya méje (aláya méje)

Fẹ́mi aláya méje (Fẹ́mi aláya méje)

Ṣùgbọ́n o adúpẹ́ lọ́wọ́ Èsúsú (adúpẹ́ lọ́wọ́ Èsúsú)

Fẹ́mi ẹni pé ẹ kú Àyìndé wọ́n á kú di o

(Ó di afọwọ́fọná afọwọ́fọná kì í ní’sinmi o)

(Wérewère ní ń jó ká ìgboro)

Afod Ọkọ Arúgbó

Ẹní pé o kú Àyìndé á kú di o

(Ó di afọwọ́fọná afọwọ́fọná kì í ní’sinmi o)

(Wérewère ní ń jó ká ìgboro)

Gbogbo yín pátá pátá Ọlọ́hun ti bá mi gbé ọwọ́ọ yín sókè

Ẹ ò ní relẹ̀ lọ́lá Ọlọ́hun Ọba ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́

Ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o (Ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o)

Ah! Ibrahim Chatta ó gbàmí lálejò sínú ilé ńlá náà

Àgbàlá ilé ńlá l’Ọ́yọ̀ọ́

Ọlọ́hun bá mi gbé ọwọ́ọ yín sókè Júù bẹ́ẹ̀ lọ

Ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o

(ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o)

Àjàní ó wù mí kó o dé Film village

Ibrahim Chatta ó ṣe bẹbẹ

Ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o

(ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o)

Afọdúnrìn ọkọ arúgbó

Ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o

(ìdùnnú Nigeria ṣá lẹ jẹ́ o)

Orìn mi Àyìndé adé

Àmọ̀pé olókun hú yáyá

Mo lọ́jọ́ a dájọ́ ijó

Bernard tí afẹ́fẹ́ ń ṣegi oko wẹ́ru wẹ́ru

Gazaz igi inú oko ń lérí

Ìràwọ̀ òní Mushin àjíná

Ó ní bó wu òjò kó balè rọ̀ o

Ó ní bójò bá le rọ̀ òun láti yalu’mi

Ẹyẹ inú oko ń ṣìpẹ̀

Ó mà ní kó má ṣe lọ bá omi ja o

Igi ò gbọ́ ó ń lérí igi pípa bá bínú

Ẹ má ṣìpẹ̀ fún abuké

Ẹ jẹ́ kígi ó ya lumi

Nínú bá b’ómi á sì gbé igi lọ ọ̀rọ̀ rèé ẹ gbe yẹ̀wò

Mo kọrin olókun hú yáyá ò ọlọ́sà ẹ mì lẹ̀ǹgbẹ̀ o

Orin àkọ́kọ́kọ́dá

Àyìnlá saliu ọmọ òkò ìrèsé

Àyìndé Fatai mi ọmọ Ayọ̀ ọlá

Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Babby

Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni Yinni

Aya Babbison o

Ọlá ọmọ Williams happy New Year to you

Bàbá mi ìná ò ní tán owó ẹ Àmín àṣẹ

Ọdún tuntun tá a bọ́sí yìí

Gbogbo nǹkan tó ti níre níre lọ̀rọ̀ atare

Ọlá ọmọ willy mi Williams

Omọ àdúgbò mi (Ọmọ àdúgbò mi o)

Olórí ẹgbẹ́ gbogbo Ajé

Ọlá ọmọ àdúgbò mi (Ọlá ọmọ àdúgbò mi o)

Ọmọ area mi ni ọmọ àdúgbò mi

(Ọlá ọmọ àdúgbò mi o)

Ọmọ Williams ọmọ àdúgbò mi

(Ọlá ọmọ àdúgbò mi o)